1. LI akoko igbana ni Herodu ọba si nawọ́ rẹ̀ lati pọn awọn kan loju ninu ijọ.
2. O si fi idà pa Jakọbu arakunrin Johanu.
3. Nigbati o si ri pe, o dùnmọ awọn Ju, o si nawọ́ mu Peteru pẹlu. O si jẹ ìgba ọjọ àiwukàra.
4. Nigbati o si mu u, o fi i sinu tubu, o fi i le ẹ̀ṣọ́ mẹrin awọn ọmọ-ogun lọwọ lati ma ṣọ ọ; o nrò lati mu u jade fun awọn enia wá lẹhin Irekọja.
5. Nitorina nwọn pa Peteru mọ́ ninu tubu: ṣugbọn ijọ nfi itara gbadura sọdọ Ọlọrun fun u.