4. Ṣugbọn Peteru bẹ̀rẹ si ilà a fun wọn lẹsẹsẹ, wipe,
5. Emi wà ni ilu Joppa, mo ngbadura: mo ri iran kan li ojuran, Ohun elo kan sọkalẹ bi gọgọwu nla, ti a ti igun mẹrẹrin sọ̀ ka ilẹ lati ọrun wá; o si wá titi de ọdọ mi:
6. Mo tẹjumọ ọ, mo si fiyesi i, mo si ri ẹran ẹlẹsẹ mẹrin aiye, ati ẹranko igbẹ́, ati ohun ti nrakò, ati ẹiyẹ oju ọrun.
7. Mo si gbọ́ ohùn kan ti o fọ̀ si mi pe, Dide, Peteru; mã pa, ki o si mã jẹ.
8. Ṣugbọn mo dahùn wipe, Agbẹdọ, Oluwa: nitori ohun èwọ tabi alaimọ́ kan kò wọ̀ ẹnu mi ri lai.
9. Ṣugbọn ohùn kan dahun lẹ̃keji lati ọrun wá pe, Ohun ti Ọlọrun ba ti wẹ̀nu, iwọ máṣe pè e li èwọ.