1. Tes 5:18-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Ẹ mã dupẹ ninu ohun gbogbo: nitori eyi ni ifẹ Ọlọrun ninu Kristi Jesu fun nyin.

19. Ẹ máṣe pa iná Ẹmí.

20. Ẹ máṣe kẹgan isọtẹlẹ.

21. Ẹ mã wadi ohun gbogbo daju; ẹ dì eyiti o dara mu ṣinṣin.

22. Ẹ mã takéte si ohun gbogbo ti o jọ ibi.

23. Ki Ọlọrun alafia tikararẹ̀ ki o sọ nyin di mimọ́ patapata; ki a si pa ẹmí ati ọkàn ati ara nyin mọ́ patapata li ailabukù ni ìgba wíwa Oluwa wa Jesu Kristi.

24. Olododo li ẹniti o pè nyin, ti yio si ṣe e.

25. Ará, ẹ mã gbadura fun wa.

26. Ẹ fi ifẹnukonu mimọ́ kí gbogbo awọn ará.

1. Tes 5