1. Sam 4:12-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Ọkunrin ara Benjamini kan sa lati ogun wá o si wá si Ṣilo lọjọ kanna, ti on ti aṣọ rẹ̀ fifaya, ati erupẹ lori rẹ̀.

13. Nigbati o si de, si wõ, Eli joko lori apoti kan lẹba ọ̀na o nṣọna: nitori aiyà rẹ̀ kò balẹ nitori apoti Ọlọrun. Ọkunrin na si wọ ilu lati rohin, gbogbo ilu fi igbe ta.

14. Eli si gbọ́ ohùn igbe na, o sì wipe, Ohùn igbe kili eyi? ọkunrin na si yara wá o si rò fun Eli.

15. Eli si di ẹni ejidilọgọrun ọdun; oju rẹ̀ di baibai, kò si le riran.

1. Sam 4