1. Sam 31:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. AWỌN Filistini si ba Israeli jà: awọn ọkunrin Israeli si sa niwaju awọn Filistini, awọn ti o fi ara pa sì ṣubu li oke Gilboa.

2. Awọn Filistini si nlepa Saulu ati awọn ọmọ rẹ̀ kikan; awọn Filistini si pa Jonatani, ati Abinadabu, ati Melkiṣua, awọn ọmọ Saulu.

3. Ijà na si buru fun Saulu gidigidi, awọn tafàtafa si ta a li ọfà, o si fi ara pa pupọ li ọwọ́ awọn tafàtafa.

4. Saulu si wi fun ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ pe, Fa ìda rẹ yọ, ki o si fi i gún mi, ki awọn alaikọla wọnyi ki o má bà wá gún mi, ati ki wọn ki o má ba fi mi ṣe ẹlẹya. Ṣugbọn ẹniti o ru ihamọra rẹ̀ ko fẹ ṣe bẹ̃, nitoripe ẹrù ba a gidigidi. Saulu si mu idà na o si fi pa ara rẹ̀.

5. Nigbati ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ si ri pe Saulu kú, on na si fi idà rẹ̀ pa ara rẹ̀, o si kú pẹlu rẹ̀.

6. Saulu si kú, ati awọn ọmọ rẹ̀ mẹta, ati ẹni ti o rù ihamọra rẹ̀, ati gbogbo awọn ọmọkunrin rẹ̀ li ọjọ kanna.

7. Nigbati awọn ọkunrin Israeli ti o wà li apa keji afonifoji na, ati awọn ẹniti o wà li apa keji Jordani, ri pe awọn ọkunrin Israeli sa, ati pe Saulu ati awọn ọmọbibi rẹ̀ si kú, nwọn si fi ilu silẹ, nwọn si sa; awọn Filistini si wá, nwọn si joko si ilu wọn.

8. O si ṣe, li ọjọ keji, nigbati awọn Filistini de lati bọ́ nkan ti mbẹ lara awọn ti o kú, nwọn si ri pe, Saulu ati awọn ọmọ rẹ̀ mẹta ṣubu li oke Gilboa,

1. Sam 31