7. Samueli ko iti mọ̀ Oluwa, bẹ̃ni a ko iti fi ọ̀rọ Oluwa hàn a.
8. Oluwa si tun Samueli pè lẹ̃kẹta. O si dide tọ Eli lọ, o si wipe, Emi nĩ; nitori iwọ pè mi. Eli, si mọ̀ pe, Oluwa li o npe ọmọ na.
9. Nitorina Eli wi fun Samueli pe, Lọ dubulẹ: yio si ṣe, bi o ba pè ọ, ki iwọ si wipe, ma wi, Oluwa; nitoriti iranṣẹ rẹ ngbọ́. Bẹ̃ni Samueli lọ, o si dubulẹ nipò tirẹ̀.
10. Oluwa wá, o si duro, o si pè bi igbá ti o kọja, Samueli, Samueli. Nigbana ni Samueli dahun pè, Ma wi; nitori ti iranṣẹ rẹ ngbọ́.
11. Oluwa si wi fun Samueli pe, Kiyesi i, emi o ṣe ohun kan ni Israeli, eyi ti yio mu eti mejeji olukuluku awọn ti o gbọ́ ọ ho.
12. Li ọjọ na li emi o mu gbogbo ohun ti mo ti sọ si ile Eli ṣẹ: nigbati mo ba bẹrẹ, emi o si ṣe e de opin.