4. Oluwa pe Samueli: on si dahun pe, Emi nĩ.
5. O si sare tọ Eli, o si wipe, Emi nĩ; nitori ti iwọ pè mi. On wipe, emi kò pè: pada lọ dubulẹ. O si lọ dubulẹ.
6. Oluwa si tun npè, Samueli. Samueli si dide tọ Eli lọ, o si wipe, Emi nĩ; nitoriti iwọ pè mi. O si da a lohun, emi kò pè, ọmọ mi; padà lọ dubulẹ.
7. Samueli ko iti mọ̀ Oluwa, bẹ̃ni a ko iti fi ọ̀rọ Oluwa hàn a.
8. Oluwa si tun Samueli pè lẹ̃kẹta. O si dide tọ Eli lọ, o si wipe, Emi nĩ; nitori iwọ pè mi. Eli, si mọ̀ pe, Oluwa li o npe ọmọ na.