1. DAFIDI si wi li ọkàn ara rẹ̀ pe, njẹ ni ijọ kan l'emi o ti ọwọ́ Saulu ṣegbe, ko si si ohun ti o yẹ mi jù ki emi ki o yara sa asala lọ si ilẹ awọn Filistini: yio su Saulu lati ma tun wá mi kiri ni gbogbo agbegbe Israeli: emi a si bọ li ọwọ́ rẹ̀.
2. Dafidi si dide, o si rekọja, on ati ẹgbẹta ọmọkunrin ti o mbẹ lọdọ rẹ̀ si Akiṣi, ọmọ Maoki, ọba Gati.