1. Sam 25:31-37 Yorùbá Bibeli (YCE)

31. Eyi ki yio si jasi ibinujẹ fun ọ, tabi ibinujẹ ọkàn fun oluwa mi, nitoripe iwọ ta ẹjẹ alaiṣẹ silẹ, tabi pe oluwa mi gbẹsan fun ara rẹ̀: ṣugbọn nigbati Oluwa ba ṣe ore fun oluwa mi, njẹ ranti iranṣẹbinrin rẹ.

32. Dafidi si wi fun Abigaili pe, Alabukun fun Oluwa Ọlọrun Israeli, ti o ran ọ loni yi lati pade mi.

33. Ibukun ni fun ọgbọn rẹ, alabukunfun si ni iwọ, ti o da mi duro loni yi lati wá ta ẹjẹ silẹ, ati lati fi ọwọ́ mi gbẹsan fun ara mi.

34. Nitõtọ bi Oluwa Ọlọrun Israeli ti mbẹ, ti o da mi duro lati pa ọ lara, bikoṣepe bi iwọ ti yara ti o si ti wá pade mi, nitotọ ki ba ti kù fun Nabali di imọlẹ owurọ ninu awọn ti o ntọ̀ sara ogiri.

35. Bẹ̃ni Dafidi si gbà nkan ti o mu wá fun u li ọwọ́ rẹ̀, o si wi fun u pe, Goke lọ li alafia si ile rẹ, wõ, emi ti gbọ́ ohun rẹ, inu mi si dùn si ọ.

36. Abigaili si tọ̀ Nabali wá, si wõ, on si se asè ni ile rẹ̀ gẹgẹ bi ase ọba; inu Nabali si dùn nitoripe, o ti mu ọti li amupara; on kò si sọ nkan fun u, diẹ tabi pupọ: titi di imọlẹ owurọ.

37. O si ṣe; li owurọ, nigbati ọti na si dá tan li oju Nabali, obinrin rẹ̀ si rò nkan wọnni fun u, ọkàn rẹ̀ si kú ninu, on si dabi okuta.

1. Sam 25