19. On si wi fun awọn ọmọkunrin rẹ̀ pe, Ma lọ niwaju mi; wõ, emi mbọ lẹhin nyin. Ṣugbọn on kò wi fun Nabali bale rẹ̀.
20. O si ṣe, bi o ti gun ori kẹtẹkẹtẹ, ti o si nsọkalẹ si ibi ikọkọ oke na, wõ, Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si nsọ-kalẹ, niwaju rẹ̀; on si wá pade wọn.
21. Dafidi si ti wipe, Njẹ lasan li emi ti pa gbogbo eyi ti iṣe ti eleyi mọ li aginju, ti ohunkohun kò si nù ninu gbogbo eyi ti iṣe tirẹ̀; on li o si fi ibi san ire fun mi yi.
22. Bẹ̃ ati ju bẹ̃ lọ ni ki Ọlọrun ki o ṣe si awọn ọta Dafidi, bi emi ba fi ẹnikẹni ti ntọ̀ sara ogiri silẹ ninu gbogbo eyi ti iṣe tirẹ̀ titi di imọlẹ owurọ.
23. Abigaili si ri Dafidi, on si yara, o sọkalẹ lori kẹtẹkẹtẹ, o si dojubolẹ niwaju Dafidi, o si tẹ ara rẹ̀ ba silẹ.