1. Sam 25:10-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Nabali si da awọn iranṣẹ Dafidi lohùn, pe, Tani ijẹ Dafidi? tabi tani si njẹ ọmọ Jesse? ọ̀pọlọpọ iranṣẹ ni mbẹ nisisiyi ti nwọn sá olukuluku kuro lọdọ oluwa rẹ̀.

11. Njẹ ki emi ki o ha mu onjẹ mi, ati omi mi, ati ẹran mi ti mo pa fun awọn olùrẹrun mi, ki emi ki o si fi fun awọn ọkunrin ti emi kò mọ̀ ibi ti nwọn gbe ti wá?

12. Bẹ̃li awọn ọmọkunrin Dafidi si mu ọ̀na wọn pọ̀n, nwọn si pada, nwọn si wá, nwọn si rò fun u gẹgẹ bi gbogbo ọ̀rọ wọnyi.

13. Dafidi si wi fun awọn ọmọkunrin rẹ̀ pe, Ki olukuluku nyin ki o di idà rẹ̀ mọ idi. Olukuluku ọkunrin si di idà rẹ̀ mọ idi; ati Dafidi pẹlu si di idà tirẹ̀: iwọn irinwo ọmọkunrin si goke tọ Dafidi lẹhin; igba si joko nibi ẹrù.

14. Ọkan ninu awọn ọmọkunrin Nabali si wi fun Abigaili aya rẹ̀ pe, Wõ, Dafidi ran onṣẹ lati aginju wá lati ki oluwa wa; o si kanra mọ wọn.

15. Ṣugbọn awọn ọkunrin na ṣe ore fun wa gidigidi, nwọn kò ṣe wa ni iwọsi kan, ohunkohun kò nù li ọwọ́ wa, ni gbogbo ọjọ ti awa ba wọn rìn nigbati awa mbẹ li oko.

16. Odi ni nwọn sa jasi fun wa lọsan, ati loru, ni gbogbo ọjọ ti a fi ba wọn gbe, ti a mbojuto awọn agutan.

17. Njẹ si ro o wò, ki o si mọ̀ eyiti iwọ o ṣe; nitoripe ati gbero ibi si oluwa wa, ati si gbogbo ile rẹ̀: on si jasi ọmọ Beliali ti a ko le sọ̀rọ fun.

18. Abigaili si yara, o si mu igba iṣu akara ati igo ọti-waini meji, ati agutan marun, ti a ti sè, ati oṣuwọn agbado yiyan marun, ati ọgọrun idi ajara, ati igba akara eso ọpọtọ, o si di wọn ru kẹtẹkẹtẹ.

1. Sam 25