1. Sam 24:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si ṣe nigbati Saulu pada kuro lẹhin awọn Filistini, a si sọ fun u pe, Wõ, Dafidi mbẹ ni aginju Engedi.

2. Saulu si mu ẹgbẹdogun akọni ọkunrin ti a yàn ninu gbogbo Israeli, o si lọ lati wá Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ lori okuta awọn ewurẹ igbẹ.

3. O si de ibi awọn agbo agutan ti o wà li ọ̀na, ihò kan si wà nibẹ, Saulu si wọ inu rẹ̀ lọ lati bo ẹsẹ rẹ̀: Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si mbẹ lẹba iho na.

4. Awọn ọmọkunrin Dafidi si wi fun u pe, Wõ, eyi li ọjọ na ti Oluwa wi fun ọ pe, Wõ, emi o fi ọta rẹ le ọ li ọwọ́, iwọ o si ṣe si i gẹgẹ bi o ti tọ li oju rẹ. Dafidi si dide, o si yọ lọ ike eti aṣọ Saulu.

5. O si ṣe lẹhin eyi, aiya já Dafidi nitoriti on ke eti aṣọ Saulu.

1. Sam 24