1. Sam 23:13-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ ti wọn to ẹgbẹta enia si dide, nwọn lọ kuro ni Keila, nwọn si lọ si ibikibi ti nwọn le lọ. A si wi fun Saulu pe, Dafidi ti sa kuro ni Keila; ko si lọ si Keila mọ.

14. Dafidi si ngbe ni aginju, nibiti o ti sa pamọ si, o si ngbe nibi oke-nla kan li aginju Sifi. Saulu si nwá a lojojumọ, ṣugbọn Ọlọrun ko fi le e lọwọ.

15. Dafidi si ri pe, Saulu ti jade lati wá ẹmi on kiri: Dafidi si wà li aginju Sifi ninu igbo kan.

16. Jonatani ọmọ Saulu si dide, o si tọ Dafidi lọ ninu igbo na, o si gba a ni iyanju nipa ti Ọlọrun.

17. On si wi fun u pe, Máṣe bẹru: nitori ọwọ́ Saulu baba mi kì yio tẹ̀ ọ: iwọ ni yio jọba lori Israeli, emi ni yio si ṣe ibikeji rẹ; Saulu baba mi mọ̀ bẹ̃ pẹlu.

18. Awọn mejeji si ṣe adehun niwaju Oluwa; Dafidi si joko ninu igbo na. Jonatani si lọ si ile rẹ̀.

19. Awọn ara Sifi si goke tọ Saulu wá si Gibea, nwọn si wipe, Ṣe Dafidi ti fi ara rẹ̀ pamọ sọdọ wa ni ibi ti o to sa pamọ si ni igbo, ni oke Hakila, ti o wà niha gusu ti Jeṣimoni?

20. Njẹ nisisiyi, Ọba, sọkalẹ wá gẹgẹ bi gbogbo ifẹ ti o wà li ọkàn rẹ lati sọkalẹ; ipa ti awa ni lati fi i le ọba lọwọ.

21. Saulu si wipe, Alabukun fun li ẹnyin nipa ti Oluwa; nitoripe ẹnyin ti kãnu fun mi.

1. Sam 23