1. NWỌN si wi fun Dafidi pe, Sa wõ awọn ara Filistia mba ara Keila jagun, nwọn si jà ilẹ ipakà wọnni li ole.
2. Dafidi si bere lọdọ Oluwa pe, Ki emi ki o lọ kọlu awọn ara Filistia wọnyi bi? Oluwa si wi fun Dafidi pe. Lọ, ki o si kọlu awọn ara Filistia ki o si gbà Keila silẹ.
3. Awọn ọmọkunrin ti o wà lọdọ Dafidi si wi fun u pe, Wõ, awa mbẹ̀ru nihinyi ni Juda; njẹ yio ti ri nigbati awa ba de Keila lati fi oju ko ogun awọn ara Filistia?