8. Ti gbogbo nyin fi dimọlù si mi, ti kò fi si ẹnikan ti o sọ ọ li eti mi pe, ọmọ mi ti ba ọmọ Jesse mulẹ, bẹ̃ni kò si si ẹnikan ninu nyin ti o ṣanu mi, ti o si sọ ọ li eti mi pe, ọmọ mi mu ki iranṣẹ mi dide si mi lati ba dè mi, bi o ti ri loni?
9. Doegi ara Edomu ti a fi jẹ olori awọn iranṣẹ Saulu, si dahun wipe, Emi ri ọmọ Jesse, o wá si Nobu, sọdọ Ahimeleki ọmọ Ahitubu.
10. On si bere lọdọ̀ Oluwa fun u, o si fun u li onjẹ o si fun u ni idà Goliati ara Filistia.
11. Ọba si ranṣẹ pe Ahimeleki alufa, ọmọ Ahitubu ati gbogbo idile baba rẹ̀, awọn alufa ti o wà ni Nobu: gbogbo wọn li o si wá sọdọ ọba.
12. Saulu si wipe, Njẹ gbọ́, iwọ ọmọ Ahitubu. On si wipe, Emi nĩ, oluwa mi.
13. Saulu si wi fun u pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi dimọlù si mi, iwọ ati ọmọ Jesse, ti iwọ fi fun u li akara, ati idà, ati ti iwọ fi bere fun u lọdọ Ọlọrun, ki on ki o le dide si mi, lati ba dè mi, bi o ti ri loni?