3. Dafidi si ti ibẹ̀ na lọ si Mispe ti Moabu: on si wi fun ọba Moabu pe, Jẹ ki baba ati iya mi, emi bẹ̀ ọ, wá ba ọ gbe, titi emi o fi mọ̀ ohun ti Ọlọrun yio ṣe fun mi.
4. O si mu wọn wá siwaju ọba Moabu; nwọn si ba a gbe ni gbogbo ọjọ ti Dafidi fi wà ninu ihò na.
5. Gadi woli si wi fun Dafidi pe, Máṣe gbe inu ihò na; yẹra, ki o si lọ si ilẹ Juda. Nigbana ni Dafidi si yẹra, o si lọ sinu igbo Hareti.
6. Saulu si gbọ́ pe a ri Dafidi ati awọn ọkunrin ti o wà lọdọ rẹ̀; Saulu si ngbe ni Gibea labẹ igi kan ni Rama; ọkọ̀ rẹ̀ si mbẹ lọwọ rẹ̀, ati gbogbo awọn iranṣẹ rẹ si duro tì i;
7. Nigbana ni Saulu wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ ti o duro tì i, pe, Njẹ, ẹ gbọ́, ẹnyin ara Benjamini, ọmọ Jesse yio ha fun olukuluku nyin ni oko ati ọgba ajara bi, ki o si sọ gbogbo nyin di olori ẹgbẹgbẹrun ati olori ọrọrun bi?