35. Emi o gbe alufa olododo kan dide, ẹniti yio ṣe gẹgẹ bi ifẹ inu mi, ati ọkàn mi; emi o si kọ ile kan ti yio duro ṣinṣin fun u; yio si ma rin niwaju ẹni-ororo mi li ọjọ gbogbo.
36. Yio si ṣe, olukuluku ẹniti o ba kù ni ile rẹ yio wá tẹriba fun u nitori fadaka diẹ, ati nitori okele onjẹ, yio si wipe, Jọwọ fi mi sinu ọkan ninu iṣẹ awọn alufa, ki emi ki o le ma ri akara diẹ jẹ.