13. Awọn mẹta ti o dàgba ninu awọn ọmọ Jesse, si tọ Saulu lẹhin lọ si oju ijà: orukọ awọn ọmọ mẹtẹta ti o lọ si ibi ijà si ni Eliabu, akọbi, atẹle rẹ̀ si ni Abinadabu, ẹkẹta si ni Ṣamma.
14. Dafidi si ni abikẹhin: awọn ẹgbọ́n iwaju rẹ̀ mẹtẹta ntọ̀ Saulu lẹhin.
15. Ṣugbọn Dafidi lọ, o si yipada lẹhin Saulu, lati ma tọju agutan baba rẹ̀ ni Betlehemu.
16. Filistini na a si ma sunmọ itosi li owurọ ati li alẹ, on si fi ara rẹ̀ han li ogoji ọjọ.
17. Jesse si wi fun Dafidi ọmọ rẹ̀ pe, Jọwọ, mu agbado didin yi ti ẹfa kan, ati iṣu akara mẹwa yi fun awọn ẹgbọn rẹ, ki o si sure tọ awọn ẹgbọn rẹ ni ibudo;
18. Ki o si mu warakasi mẹwa wọnyi fun oloriogun ẹgbẹrun wọn, ki o si wo bi awọn ẹgbọn rẹ ti nṣe, ki o si gbà nkan àmi wọn wá.
19. Saulu, ati awọn, ati gbogbo ọkunrin Israeli si wà ni afonifoji Ela, nwọn mba awọn Filistini jà.
20. Dafidi si dide ni kutukutu owurọ, o si fi agutan wọnni le olutọju kan lọwọ, o si mura, o si lọ, gẹgẹ bi Jesse ti fi aṣẹ fun u; on si de ibi yàra, ogun na si nlọ si oju ijà, nwọn hó iho ogun.
21. Israeli ati Filistini si tẹgun, ogun si pade ogun.
22. Dafidi si fi nkan ti o nmu lọ le ọkan ninu awọn olutọju nkan gbogbo lọwọ, o si sare si ogun, o tọ awọn ẹgbọn rẹ̀ lọ, o si ki wọn.
23. Bi on si ti mba wọn sọ̀rọ, sa wõ, akikanju ọkunrin na, Filistini ti Gati, ti orukọ rẹ̀ njẹ Goliati si goke wá, lati ogun awọn Filistini, o si sọ gẹgẹ bi ọ̀rọ ti o ti nsọ ri: Dafidi si gbọ́.