8. O si mu Agagi Ọba Amaleki lãye, o si fi oju ida run gbogbo awọn enia na.
9. Ṣugbọn Saulu ati awọn enia na da Agagi si, ati eyi ti o dara julọ ninu agutan ati ninu malu, ati ohun eyi ti o dara tobẹ̃ ninu wọn, ati ọdọ-agutan abọpa, ati gbogbo nkan ti o dara; nwọn kò si fẹ pa wọn run: ṣugbọn gbogbo nkan ti kò dara ti kò si nilari ni nwọn parun patapata.
10. Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ Samueli wá wipe,
11. Emi kãnu gidigidi ti emi fi Saulu jọba: nitoriti o ti yipada lẹhin mi, kò si mu ọ̀rọ mi ṣẹ. O si ba Samueli ninu jẹ gidigidi; on si kepe Oluwa ni gbogbo oru na.
12. Nigbati Samueli si dide ni kutukutu owurọ̀ lati pade Saulu, nwọn si sọ fun Samueli pe, Saulu ti wá si Karmeli, sa wõ, on kọ ibi kan fun ara rẹ̀ o si ti lọ, o si kọja siwaju, o si sọkalẹ lọ si Gilgali.