42. Saulu si wipe, Di ibò ti emi ati ti Jonatani ọmọ mi. Ibò na si mu Jonatani.
43. Saulu si wi fun Jonatani pe, Sọ nkan ti o ṣe fun mi. Jonatani si sọ fun u, o si wipe, Nitõtọ mo fi ori ọ̀pá ti mbẹ li ọwọ́ mi tọ́ oyin diẹ wò, wõ emi mura ati kú.
44. Saulu si wipe, ki Ọlọrun ki o ṣe bẹ̃ ati ju bẹ̃ lọ pẹlu: nitoripe iwọ Jonatani yio sa kú dandan.
45. Awọn enia si wi fun Saulu pe, Jonatani yio kú, ti o ṣe igbala nla yi ni Israeli? ki a má ri i; bi Oluwa ti wà, ọkan ninu irun ori rẹ̀ kì yio bọ́ silẹ; nitoripe o ba Ọlọrun ṣiṣẹ pọ̀ loni. Bẹ̃li awọn enia si gbà Jonatani silẹ, kò si kú.
46. Saulu si ṣiwọ ati ma lepa awọn Filistini: Awọn Filistini si lọ si ilu wọn.