30. A! nitotọ, ibaṣepe awọn enia na ti jẹ ninu ikogun awọn ọta wọn ti nwọn ri, pipa awọn Filistini iba ti pọ to?
31. Nwọn pa ninu awọn Filistini li ọjọ na, lati Mikmaṣi de Aijaloni: o si rẹ̀ awọn enia na gidigidi.
32. Awọn enia sare si ikogun na, nwọn si mu agutan, ati malu, ati ọmọ-malu, nwọn si pa wọn sori ilẹ: awọn enia na si jẹ wọn t'ẹjẹ t'ẹjẹ.
33. Nigbana ni nwọn wi fun Saulu pe, kiye si i, awọn enia na dẹ̀ṣẹ si Oluwa, li eyi ti nwọn jẹ ẹjẹ. On si wipe, Ẹnyin ṣẹ̀ kọja: yi okuta nla fun mi wá loni.
34. Saulu si wipe, Ẹ tu ara nyin ka sarin awọn enia na ki ẹ si wi fun wọn pe, Ki olukuluku ọkunrin mu malu tirẹ̀ tọ̀ mi wá, ati olukuluku ọkunrin agutan rẹ̀, ki ẹ si pa wọn nihin, ki ẹ si jẹ, ki ẹ má si ṣẹ̀ si Oluwa, ni jijẹ ẹjẹ. Gbogbo enia olukuluku ọkunrin mu malu rẹ̀ wá li alẹ na, nwọn si pa wọn ni ibẹ̀.
35. Saulu si tẹ pẹpẹ kan fun Oluwa; eyi ni pẹpẹ ti o kọ ṣe fun Oluwa.