2. Si wõ, nisisiyi, ọba na nrìn niwaju nyin: emi si ti di arugbo, mo si hewu; si wõ, awọn ọmọ mi si mbẹ lọdọ nyin: emi ti nrìn niwaju nyìn lati igba ewe mi wá titi o fi di oni yi.
3. Wõ, emi nĩ, jẹri si mi niwaju Oluwa, ati niwaju ẹni ami-ororo rẹ̀: malu tani mo gbà ri? tabi kẹtẹkẹtẹ tani mo gbà ri? tani mo rẹjẹ ri? tani mo jẹ ni ìya ri? tabi lọwọ́ tali emi gbà owo abẹtẹlẹ kan ri lati fi bo ara mi loju? emi o si sãn pada fun nyin.
4. Nwọn si wipe, Iwọ kò rẹ́ wa jẹ ri, bẹ̃ni iwọ kò jẹ ni ni ìya ri, bẹ̃ni iwọ ko gbà nkan lọwọ́ ẹnikẹni wa ri.
5. O si wi fun wọn pe, Oluwa li ẹlẹri si nyin, ati ẹni ami-ororo rẹ̀ ni ẹlẹri loni pe, ẹnyin kò rí nkan lọwọ́ mi. Nwọn si dahùn wipe, On li ẹlẹri.
6. Samueli si wi fun awọn enia na pe, Oluwa li ẹniti o ti yan Mose ati Aaroni, on li ẹni ti o si mu awọn baba nyin goke ti ilẹ Egipti wá.
7. Njẹ nisisiyi ẹ duro jẹ, ki emi ki o le ba nyin sọ̀rọ niwaju Oluwa niti gbogbo iṣẹ ododo Oluwa, eyi ti on ti ṣe fun nyin ati fun awọn baba nyin.