1. NITORINA ẹ fi arankàn gbogbo lelẹ li apakan, ati ẹ̀tan gbogbo, ati agabagebe, ati ilara, ati sisọ ọ̀rọ buburu gbogbo.
2. Bi ọmọ-ọwọ titun, ki ẹ mã fẹ wàra ti Ẹmí na eyiti kò li ẹ̀tan, ki ẹnyin ki o le mã ti ipasẹ rẹ̀ dàgba si igbala,
3. Bi ẹnyin ba ti tọ́ ọ wò pe, olõre li Oluwa: