6. Ati ninu awọn ọmọ Sera, Jegueli, ati awọn arakunrin wọn, ẹdẹgbẹrin o di mẹwa.
7. Ati ninu awọn ọmọ Benjamini; Sallu, ọmọ Meṣullamu, ọmọ Hodafiah, ọmọ Senua.
8. Ati Ibneiah ọmọ Jerohamu, ati Ela ọmọ Ussi, ọmọ Mikri, ati Meṣullamu ọmọ Ṣefatiah, ọmọ Regueli, ọmọ Ibniah;
9. Ati awọn arakunrin wọn, gẹgẹ bi idile wọn ẹgbẹrun o din mẹrinlelogoji. Gbogbo awọn ọkunrin wọnyi ni olori ninu awọn baba ni ile baba wọn.
10. Ati ninu awọn alufa; Jedaiah, ati Jehoiaribu ati Jakini,