4. Utai ọmọ Ammihudi, ọmọ Omri, ọmọ Imri, ọmọ Bani, ninu awọn ọmọ Faresi ọmọ Juda.
5. Ati ninu awọn ara Ṣilo, Asaiah akọbi, ati awọn ọmọ rẹ̀.
6. Ati ninu awọn ọmọ Sera, Jegueli, ati awọn arakunrin wọn, ẹdẹgbẹrin o di mẹwa.
7. Ati ninu awọn ọmọ Benjamini; Sallu, ọmọ Meṣullamu, ọmọ Hodafiah, ọmọ Senua.
8. Ati Ibneiah ọmọ Jerohamu, ati Ela ọmọ Ussi, ọmọ Mikri, ati Meṣullamu ọmọ Ṣefatiah, ọmọ Regueli, ọmọ Ibniah;