4. Ati Abiṣua, ati Naamani, ati Ahoa,
5. Ati Gera, ati Ṣefufani, ati Huramu,
6. Wọnyi si li awọn ọmọ Ehudi: wọnyi li awọn olori baba wọn, ti nwọn ngbe Geba, nwọn si ko wọn lọ si Mahanati ni igbekun.
7. Ati Naamani, ati Ahiah, ati Gera, o si ko wọn kuro, o si bi Ussa ati Ahihudi.
8. Ṣaharaimu si bi ọmọ ni ilẹ Moabu; lẹhin igbati o ti ran wọn lọ tan; Huṣimu ati Baera si li awọn aya rẹ̀.
9. Hodeṣi, aya rẹ̀ si bi, Jobabu, ati Sibia, ati Meṣa, ati Malkama fun u,