1. BENJAMINI si bi Bela, akọbi rẹ̀, Aṣbeli ekeji, ati Ahara ẹkẹta,
2. Noha ẹkẹrin, ati Rafa ẹkarun.
3. Awọn ọmọ Bela ni Addari, ati Gera, ati Abihudi,
4. Ati Abiṣua, ati Naamani, ati Ahoa,
5. Ati Gera, ati Ṣefufani, ati Huramu,
6. Wọnyi si li awọn ọmọ Ehudi: wọnyi li awọn olori baba wọn, ti nwọn ngbe Geba, nwọn si ko wọn lọ si Mahanati ni igbekun.
7. Ati Naamani, ati Ahiah, ati Gera, o si ko wọn kuro, o si bi Ussa ati Ahihudi.