1. Kro 4:8-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Kosi si bi Anubu, ati Sobeba, ati awọn idile Aharheli, ọmọ Harumu.

9. Jabesi si ṣe ọlọla jù awọn arakunrin rẹ̀ lọ: iya rẹ̀ si pe orukọ rẹ̀ ni Jabesi, wipe, Nitoriti mo bi i pẹlu ibanujẹ.

10. Jabesi si ké pè Ọlọrun Israeli, wipe, Iwọ iba jẹ bukún mi nitõtọ, ki o si sọ àgbegbe mi di nla, ki ọwọ rẹ ki o si wà pẹlu mi, ati ki iwọ ki o má si jẹ ki emi ri ibi, ki emi má si ri ibinujẹ! Ọlọrun si mu ohun ti o tọrọ ṣẹ.

11. Kelubu arakunrin Ṣua si bi Mehiri, ti iṣe baba Eṣtoni.

12. Eṣtoni si bi Bet-rafa, ati Pasea, ati Tehinna baba ilu Nahaṣi. Wọnyi li awọn ọkunrin Reka,

13. Ati awọn ọmọ Kenasi; Otnieli, ati Seraiah: ati awọn ọmọ Otnieli; Hatati.

14. Meonotai si bi Ofra: Seraiah si bi Joabu, baba Geharasimu; nitori oniṣọnà ni nwọn.

15. Ati awọn ọmọ Kalebu ọmọ Jefunne; Iru, Ela, ati Naamu: ati awọn ọmọ Ela, ani Kenasi.

16. Ati awọn ọmọ Jehaleleeli; Sifu, ati Sifa, Tiria, ati Asareeli.

17. Ati awọn ọmọ Esra ni Jeteri, ati Meredi, ati Eferi, ati Jaloni: on si bi Miriamu, ati Ṣammai, ati Iṣba baba Eṣtemoa.

1. Kro 4