21. Nwọn si ru ẹbọ si Oluwa, nwọn si ru ẹbọ sisun si Oluwa, li ọjọ keji lẹhin ọjọ na, ẹgbẹrun akọmalu, ẹgbẹrun àgbo, ẹgbẹrun ọdọ-agutan, pẹlu ọrẹ mimu wọn, ati ẹbọ miran li ọ̀pọlọpọ fun gbogbo Israeli:
22. Nwọn si jẹ nwọn si mu niwaju Oluwa li ọjọ na pẹlu ayọ̀ nla. Nwọn si tun fi Solomoni ọmọ Dafidi jọba li ẹ̃keji, a si fi ororo yàn a li ọba, ati Sadoku li alufa.
23. Bẹ̃ni Solomoni joko lori itẹ Oluwa bi ọba ni ipò Dafidi baba rẹ̀, o si pọ̀ si i; gbogbo Israeli si gba tirẹ̀ gbọ́.
24. Ati gbogbo awọn ijoye, ati awọn alagbara, ati pẹlu gbogbo awọn ọmọ Dafidi ọba tẹri wọn ba fun Solomoni ọba.
25. Oluwa si gbé Solomoni ga gidigidi li oju gbogbo Israeli, o si fi ọlá nla ọba fun u bi iru eyi ti kò wà fun ọba kan ṣaju rẹ̀ lori Israeli.
26. Dafidi ọmọ Jesse si jọba lori gbogbo Israeli.
27. Akokò ti o si fi jọba lori Israeli jẹ ogoji ọdun; ọdun meje li o jọba ni Hebroni, ati mẹtalelọgbọn li o jọba ni Jerusalemu.
28. On si darugbó, o kú rere, o kún fun ọjọ, ọrọ̀ ati ọlá; Solomoni ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.
29. Njẹ iṣe Dafidi ọba, ibẹ̀rẹ ati ikẹhin, kiyesi i, a kọ ọ sinu iwe Samueli ariran, ati sinu iwe itan Natani woli, ati sinu iwe itan Gadi ariran.
30. Pẹlu gbogbo jijọba ati ipá rẹ̀, ati ìgba ti o kọja lori rẹ̀, ati lori Israeli, ati lori gbogbo ijọba ilẹ wọnni.