13. Njẹ nisisiyi, Ọlọrun wa, awa dupẹ lọwọ rẹ, a si yìn orukọ ogo rẹ.
14. Ṣugbọn tali emi, ati kili awọn enia mi, ti a fi le ṣe iranlọwọ tinutinu bi iru eyi? nitori ohun gbogbo ọdọ rẹ ni ti wá, ati ninu ohun ọwọ rẹ li awa ti fi fun ọ.
15. Nitori alejo ni awa niwaju rẹ, ati atipo bi gbogbo awọn baba wa: ọjọ wa li aiye dabi ojiji, kò si si ireti.
16. Oluwa Ọlọrun wa, gbogbo ohun ọ̀pọlọpọ yi ti awa ti pèse silẹ lati kọ ile fun ọ fun orukọ rẹ mimọ́, lati ọwọ rẹ wá ni, ati gbogbo rẹ̀ jẹ tirẹ.
17. Emi mọ̀ pẹlu, Ọlọrun mi, pe iwọ ndan ọkàn wò, iwọ si ni inudidún si ododo. Bi o ṣe ti emi, ninu ododo ọkàn mi li emi ti fi tinutinu ṣe iranlọwọ gbogbo nkan wọnyi; ati nisisiyi pẹlu ayọ̀ ni mo ti ri awọn enia rẹ ti o wá nihin, lati fi tinutinu ṣe iranlọwọ fun ọ.
18. Oluwa Ọlọrun Abrahamu, Isaaki ati Israeli, awọn baba wa, pa eyi mọ́ lailai sinu ete ironu ọkàn awọn enia rẹ, si fi idi ọkàn wọn mulẹ si ọdọ rẹ:
19. Si fi ọkàn pipe fun Solomoni ọmọ mi lati pa ofin rẹ, ẹri rẹ, ati ilana rẹ mọ́, ati lati ṣe ohun gbogbo, ati lati kọ́ ãfin, fun eyi ti mo ti pèse silẹ.
20. Dafidi si sọ fun gbogbo ijọ enia pe, Nisisiyi ẹ fi iyìn fun Oluwa Ọlọrun nyin. Gbogbo enia si fi iyìn fun Oluwa Ọlọrun awọn baba wọn, nwọn si tẹ ori wọn ba, nwọn wolẹ fun Oluwa ati ọba.
21. Nwọn si ru ẹbọ si Oluwa, nwọn si ru ẹbọ sisun si Oluwa, li ọjọ keji lẹhin ọjọ na, ẹgbẹrun akọmalu, ẹgbẹrun àgbo, ẹgbẹrun ọdọ-agutan, pẹlu ọrẹ mimu wọn, ati ẹbọ miran li ọ̀pọlọpọ fun gbogbo Israeli: