1. Kro 28:19-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

19. Gbogbo eyi wà ninu iwe lati ọwọ Oluwa ẹniti o kọ́ mi niti gbogbo iṣẹ apẹrẹ wọnyi.

20. Dafidi si sọ fun Solomoni ọmọ rẹ̀ pe, murale ki o si gboyà, ki o si ṣiṣẹ: má bẹ̀ru, bẹ̃ni ki o máṣe dãmu: nitori Oluwa Ọlọrun, ani Ọlọrun mi wà pẹlu rẹ; on kì yio yẹ̀ ọ, bẹ̃ni kì yio kọ̀ ọ silẹ titi iwọ o fi pari gbogbo iṣẹ fun ìsin ile Oluwa.

21. Si kiyesi i, ipin awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi, wà pẹlu rẹ fun oniruru ìsin ile Ọlọrun: iwọ ni pẹlu rẹ oniruru enia, ọlọkàn fifẹ, ẹniti o ni oye gbogbo iṣẹ fun oniruru iṣẹ: pẹlupẹlu awọn ijoye ati gbogbo awọn enia wà pẹlu rẹ fun gbogbo ọ̀ran rẹ.

1. Kro 28