6. Eyini ni Benaiah na, akọni enia, ninu awọn ọgbọ̀n, o si jẹ olori awọn ọgbọ̀n: Amisabadi ọmọ rẹ̀ si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.
7. Olori ogun kẹrin fun oṣù kẹrin ni Asaheli arakunrin Joabu, ati Sebadiah ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.
8. Olori ogun karun fun oṣù karun ni Ṣamhuti ara Israhi: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.
9. Olori ogun kẹfa fun oṣù kẹfa ni Ira ọmọ Ikkeṣi ara Tekoi: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.