3. Ninu awọn ọmọ Peresi on ni olori fun gbogbo awọn olori ogun ti oṣù ekini.
4. Ati lori ẹgbẹ ti oṣù keji ni Dodai ara Ahohi, ati ẹgbẹ tirẹ̀; Mikloti pẹlu nṣe balogun: ẹgbã mejila li o wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀ pẹlu.
5. Olori ogun kẹta fun oṣù kẹta ni Benaiah ọmọ Jehoiada alufa, olori kan: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.
6. Eyini ni Benaiah na, akọni enia, ninu awọn ọgbọ̀n, o si jẹ olori awọn ọgbọ̀n: Amisabadi ọmọ rẹ̀ si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.
7. Olori ogun kẹrin fun oṣù kẹrin ni Asaheli arakunrin Joabu, ati Sebadiah ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.
8. Olori ogun karun fun oṣù karun ni Ṣamhuti ara Israhi: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.
9. Olori ogun kẹfa fun oṣù kẹfa ni Ira ọmọ Ikkeṣi ara Tekoi: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.
10. Olori ogun keje fun oṣù keje ni Heleṣi ara Peloni, ninu awọn ọmọ Efraimu: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.