1. Kro 27:28-34 Yorùbá Bibeli (YCE)

28. Ati lori igi-olifi, ati igi-sikamore ti mbẹ ni pẹ̀tẹlẹ ni Baal-hanani ara Gederi wà; ati lori iṣura ororo ni Joaṣi wà.

29. Ati lori awọn agbo malu ti njẹ̀ ni Ṣaroni ni Ṣitrai ara Ṣaroni wà: ati lori agbo malu ti o wà li afonifoji ni Ṣafati ọmọ Adlai wà:

30. Ati lori ibakasiẹ ni Obili ara Iṣmaeli wà: ati lori abo kẹtẹkẹtẹ ni Jehodaiah ara Meronoti wà:

31. Ati lori agbo agutan ni Jasisi ara Hageri wà. Gbogbo awọn wọnyi ni ijoye ohun ini ti iṣe ti Dafidi ọba.

32. Jonatani ẹgbọn Dafidi pẹlu ni ìgbimọ ọlọgbọ́n enia ati akọwe: ati Jehueli ọmọ Hakmoni wà pẹlu awọn ọmọ ọba.

33. Ahitofeli si jẹ ìgbimọ ọba: ati Huṣai ara Arki ni ọrẹ ọba.

34. Ati lẹhin Ahitofeli ni Jehoiada ọmọ Benaiah, ati Abiatari: Joabu si ni arẹ-balogun ogun ọba.

1. Kro 27