6. Gbogbo awọn wọnyi li o wà labẹ ọwọ baba wọn, fun orin ile Oluwa, pẹlu kimbali, psalteri ati duru, fun ìsin ile Ọlọrun: labẹ ọwọ ọba, ni Asafu, Jedutuni, ati Hemani wà.
7. Bẹ̃ni iye wọn, pẹlu awọn arakunrin wọn ti a kọ́ li orin Oluwa, ani gbogbo awọn ti o moye, jasi ọrinlugba o le mẹjọ.
8. Nwọn si ṣẹ keké fun iṣẹ; gbogbo wọn bakanna bi ti ẹni-kekere bẹ̃ni ti ẹni-nla, ti olukọ bi ti ẹniti a nkọ́.
9. Iṣẹkeké ekini si jade wá fun Asafu si Josefu: ekeji si Gedaliah, ẹniti on pẹlu awọn arakunrin rẹ̀ ati awọn ọmọ rẹ̀, jẹ mejila:
10. Ẹkẹta si Sakkuri, awọn ọmọ rẹ̀ ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
11. Ẹkẹrin si Isri, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
12. Ẹkarun si Netaniah, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
13. Ẹkẹfa si Bukkiah, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
14. Ekeje si Jeṣarela, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
15. Ẹkẹjọ si Jeṣaiah, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
16. Ẹkẹsan si Mattaniah, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
17. Ẹkẹwa si Ṣimei, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
18. Ẹkọkanla si Asareeli, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
19. Ekejila si Haṣabiah, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
20. Ẹkẹtala si Ṣubaeli, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
21. Ẹkẹrinla si Mattitiah, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
22. Ẹkẹ̃dogun si Jeremoti, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila: