17. Awọn ọmọ Elieseri ni Rehabiah olori. Elieseri kò si li ọmọ miran; ṣugbọn awọn ọmọ Rehabiah pọ̀ gidigidi.
18. Ninu awọn ọmọ Ishari; Ṣelomiti li olori.
19. Ninu awọn ọmọ Hebroni: Jeriah ekini, Amariah ekeji, Jahasieli ẹkẹta, ati Jekamami ẹkẹrin.
20. Ninu awọn ọmọ Ussieli: Mika ekini, ati Jesiah ekeji.
21. Awọn ọmọ Merari; Mali ati Muṣi. Awọn ọmọ Mali; Eleasari ati Kiṣi.
22. Eleasari kú, kò si li ọmọkunrin bikòṣe ọmọbinrin: awọn arakunrin wọn awọn ọmọ Kiṣi si fẹ wọn li aiya.
23. Awọn ọmọ Muṣi; Mali, ati Ederi, ati Jeremoti, mẹta.
24. Wọnyi ni awọn ọmọ Lefi, bi ile baba wọn; ani olori awọn baba, bi a ti ka wọn ni iye orukọ, nipa ori wọn, awọn ti o ṣiṣẹ ìsin ile Oluwa, lati iwọn ogun ọdun ati jù bẹ̃ lọ.