1. Kro 23:1-3 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBATI Dafidi gbó, ti o si kún fun ọjọ, o fi Solomoni ọmọ rẹ̀ jẹ ọba lori Israeli.

2. O si kó gbogbo awọn ijoye Israeli jọ, ati awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi.

3. A si ka awọn ọmọ Lefi lati ẹni ọgbọ̀n ọdun ati jù bẹ̃ lọ: iye wọn nipa ori wọn, ọkunrin kọkan sí jẹ ẹgbã mọkandilogun.

1. Kro 23