15. Ọlọrun si ran angeli kan si Jerusalemu lati run u: bi o si ti nrun u, Oluwa wò, o si kãnu nitori ibi na, o si wi fun angeli na ti nrun u pe; O to, da ọwọ rẹ duro. Angeli Oluwa na si duro nibi ilẹ-ipaka Ornani, ara Jebusi.
16. Dafidi si gbé oju rẹ̀ soke, o si ri angeli Oluwa na duro lagbedemeji aiye ati ọrun, o ni idà fifayọ lọwọ rẹ̀ ti o si nà sori Jerusalemu. Nigbana ni Dafidi ati awọn àgbagba Israeli, ti o wọ aṣọ ọ̀fọ, da oju wọn bolẹ.
17. Dafidi si wi fun Ọlọrun pe, Emi kọ́ ha paṣẹ lati kaye awọn enia? ani emi li ẹniti o ṣẹ̀ ti mo si ṣe buburu pãpã; ṣugbọn bi o ṣe ti agutan wọnyi, kini nwọn ṣe? Emi bẹ̀ ọ, Oluwa Ọlọrun mi, jẹ ki ọwọ rẹ ki o wà li ara mi, ati lara ile baba mi; ṣugbọn ki o máṣe li ara awọn enia rẹ ti a o fi arùn kọlu wọn.
18. Nigbana ni angeli Oluwa na paṣẹ fun Gadi lati sọ fun Dafidi pe, ki Dafidi ki o gòke lọ ki o si tẹ pẹpẹ kan fun Oluwa, ni ilẹ ipaka Ornani, ara Jebusi.
19. Dafidi si gòke lọ nipa ọ̀rọ Gadi, ti o sọ li orukọ Oluwa.
20. Ornani si yipada, o si ri angeli na; ati awọn ọmọ rẹ̀ mẹrin pẹlu rẹ̀ pa ara wọn mọ́. Njẹ Ornani npa ọka lọwọ.