1. Kro 21:14-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Bẹ̃ li Oluwa ran ajakalẹ arun si Israeli: awọn ti o ṣubu ni Israeli jẹ ẹgbã marundilogoji enia.

15. Ọlọrun si ran angeli kan si Jerusalemu lati run u: bi o si ti nrun u, Oluwa wò, o si kãnu nitori ibi na, o si wi fun angeli na ti nrun u pe; O to, da ọwọ rẹ duro. Angeli Oluwa na si duro nibi ilẹ-ipaka Ornani, ara Jebusi.

16. Dafidi si gbé oju rẹ̀ soke, o si ri angeli Oluwa na duro lagbedemeji aiye ati ọrun, o ni idà fifayọ lọwọ rẹ̀ ti o si nà sori Jerusalemu. Nigbana ni Dafidi ati awọn àgbagba Israeli, ti o wọ aṣọ ọ̀fọ, da oju wọn bolẹ.

17. Dafidi si wi fun Ọlọrun pe, Emi kọ́ ha paṣẹ lati kaye awọn enia? ani emi li ẹniti o ṣẹ̀ ti mo si ṣe buburu pãpã; ṣugbọn bi o ṣe ti agutan wọnyi, kini nwọn ṣe? Emi bẹ̀ ọ, Oluwa Ọlọrun mi, jẹ ki ọwọ rẹ ki o wà li ara mi, ati lara ile baba mi; ṣugbọn ki o máṣe li ara awọn enia rẹ ti a o fi arùn kọlu wọn.

18. Nigbana ni angeli Oluwa na paṣẹ fun Gadi lati sọ fun Dafidi pe, ki Dafidi ki o gòke lọ ki o si tẹ pẹpẹ kan fun Oluwa, ni ilẹ ipaka Ornani, ara Jebusi.

19. Dafidi si gòke lọ nipa ọ̀rọ Gadi, ti o sọ li orukọ Oluwa.

20. Ornani si yipada, o si ri angeli na; ati awọn ọmọ rẹ̀ mẹrin pẹlu rẹ̀ pa ara wọn mọ́. Njẹ Ornani npa ọka lọwọ.

21. Bi Dafidi si ti de ọdọ Ornani, Ornani si wò, o si ri Dafidi, o si ti ibi ilẹ ipaka rẹ̀ jade, o si wolẹ, o dojubolẹ fun Dafidi.

22. Dafidi si wi fun Ornani pe, Fun mi ni ibi ipaka yi, ki emi ki o le tẹ pẹpẹ kan nibẹ fun Oluwa; iwọ o si fi fun mi ni iye owo rẹ̀ pipe; ki a le da ajakalẹ arun duro lọdọ awọn enia.

23. Ornani si wi fun Dafidi pe, Mu u fun ra rẹ, si jẹ ki oluwa mi ọba ki o ṣe eyiti o dara loju rẹ̀: wò o mo fi awọn malu pẹlu fun ẹbọ-ọrẹ-sisun, ati ohun èlo ipaka fun igi, ati ọka fun ọrẹ onjẹ; mo fi gbogbo rẹ̀ fun ọ.

24. Dafidi ọba si wi fun Ornani pe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn emi a rà a ni iye owo rẹ̀ pipe nitõtọ, nitoriti emi kì o mu eyi ti iṣe tirẹ fun Oluwa, bẹ̃ni emi kì o ru ẹbọ-ọrẹ sisun laiṣe inawo.

25. Bẹ̃ni Dafidi fi ẹgbẹta ṣekeli wura nipa iwọn fun Ornani fun ibẹ na.

26. Dafidi si tẹ pẹpẹ kan nibẹ fun Oluwa, o si ru ẹbọ ọrẹ-sisun ati ẹbọ ọpẹ, o si kepe Oluwa; on si fi iná da a li ohùn lati ọrun wá lori pẹpẹ ẹbọ-ọrẹ sisun na.

27. Oluwa si paṣẹ fun angeli na; on si tun tẹ ida rẹ̀ bọ inu akọ rẹ̀.

28. Li akokò na nigbati Dafidi ri pe Oluwa ti da on li ohùn ni ibi ilẹ-ipaka Ornani, ara Jebusi, o si rubọ nibẹ.

29. Nitori agọ Oluwa ti Mose pa li aginju, ati pẹpẹ ọrẹ sisun, mbẹ ni ibi giga ni Gibeoni li akokò na.

1. Kro 21