13. Dafidi si wi fun Gadi pe, iyọnu nla ba mi: jẹ ki emi ki o ṣubu si ọwọ Oluwa nisisiyi: nitori ãnu rẹ̀ pọ̀; ṣugbọn má jẹ ki emi ṣubu si ọwọ ẹnia.
14. Bẹ̃ li Oluwa ran ajakalẹ arun si Israeli: awọn ti o ṣubu ni Israeli jẹ ẹgbã marundilogoji enia.
15. Ọlọrun si ran angeli kan si Jerusalemu lati run u: bi o si ti nrun u, Oluwa wò, o si kãnu nitori ibi na, o si wi fun angeli na ti nrun u pe; O to, da ọwọ rẹ duro. Angeli Oluwa na si duro nibi ilẹ-ipaka Ornani, ara Jebusi.
16. Dafidi si gbé oju rẹ̀ soke, o si ri angeli Oluwa na duro lagbedemeji aiye ati ọrun, o ni idà fifayọ lọwọ rẹ̀ ti o si nà sori Jerusalemu. Nigbana ni Dafidi ati awọn àgbagba Israeli, ti o wọ aṣọ ọ̀fọ, da oju wọn bolẹ.
17. Dafidi si wi fun Ọlọrun pe, Emi kọ́ ha paṣẹ lati kaye awọn enia? ani emi li ẹniti o ṣẹ̀ ti mo si ṣe buburu pãpã; ṣugbọn bi o ṣe ti agutan wọnyi, kini nwọn ṣe? Emi bẹ̀ ọ, Oluwa Ọlọrun mi, jẹ ki ọwọ rẹ ki o wà li ara mi, ati lara ile baba mi; ṣugbọn ki o máṣe li ara awọn enia rẹ ti a o fi arùn kọlu wọn.