1. Kro 20:1-3 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O SI ṣe lẹhin igbati ọdun yipo, li akokò ti awọn ọba lọ si ogun; Joabu si gbé agbara ogun jade, o si ba ilu awọn ọmọ Ammoni jẹ, nwọn si wá, nwọn si do tì Rabba. Ṣugbọn Dafidi duro ni Jerusalemu. Joabu si kọlù Rabba o si pa a run.

2. Dafidi si gbà ade ọba wọn kuro lori rẹ̀, o si ri i pe o wọ̀n talenti wura kan, okuta iyebiye si wà lara rẹ̀; a si fi de Dafidi li ori: o si kó ikogun pipọpipọ lati inu ilu na wá.

3. O si kó awọn enia ti o wà nibẹ jade wá, o si fi ayùn ati irin mimu ati ãke ké wọn. Aní bayi ni Dafidi ṣe si gbogbo ilu awọn ọmọ Ammoni. Ati Dafidi ati gbogbo awọn enia pada bọ̀ si Jerusalemu.

1. Kro 20