28. Awọn ọmọ Onamu si ni, Ṣammai, ati Jada. Awọn ọmọ Ṣammai ni; Nadabu ati Abiṣuri.
29. Orukọ aya Abiṣuri si njẹ Abihaili, on si bi Abani, ati Molidi fun u.
30. Ati awọn ọmọ Nadabu; Seledi, ati Appaimu: ṣugbọn Seledi kú laini ọmọ.
31. Ati awọn ọmọ Appaimu; Iṣi. Ati awọn ọmọ Iṣi; Ṣeṣani. Ati awọn ọmọ Ṣeṣani. Ahlai.
32. Ati awọn ọmọ Jada arakunrin Ṣammai; Jeteri, ati Jonatani; Jeteri si kú laini ọmọ.
33. Awọn ọmọ Jonatani; Peleti, ati Sasa. Wọnyi ni awọn ọmọ Jerahmeeli.
34. Ṣeṣani kò si ni ọmọkunrin, bikọṣe ọmọbinrin. Ṣeṣani si ni iranṣẹ kan, ara Egipti, orukọ, ẹniti ijẹ Jarha.