1. WỌNYI ni awọn ọmọ Israeli; Rubeni, Simeoni, Lefi, ati Juda, Issakari, ati Sebuluni,
2. Dani, Josefu, ati Benjamini, Naftali, Gadi, ati Aṣeri.
3. Awọn ọmọ Juda; Eri, ati Onani, ati Ṣela; awọn mẹta yi ni Batṣua, ara Kenaani, bi fun u. Eri, akọbi Juda, si buru loju Oluwa; on si pa a.
4. Tamari aya-ọmọ rẹ̀ si bi Faresi ati Sera fun u. Gbogbo awọn ọmọ Juda jẹ marun.