1. Kro 18:5-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Nigbati awọn ara Siria ti Damasku wá lati ran Hadareseri ọba Soba lọwọ, Dafidi pa ẹgbã mọkanla enia ninu awọn ara Siria.

6. Dafidi si fi ẹgbẹ-ogun si Siria ti Damasku; awọn ara Siria si di iranṣẹ Dafidi, nwọn si mu ọrẹ wá. Bayi li Oluwa gbà Dafidi nibikibi ti o ba nlọ.

7. Dafidi si gbà awọn asa wura ti mbẹ lara awọn iranṣẹ Hadareseri, o si mu wọn wá si Jerusalemu.

8. Lati Tibhati pẹlu ati lati Kuni, ilu Hadareseri ni Dafidi ko ọ̀pọlọpọ idẹ, eyiti Solomoni fi ṣe okun idẹ, ọwọn wọnni, ati ohun elo idẹ wọnni.

9. Nigbati Tou ọba Hamati gbọ́ pe Dafidi ti pa gbogbo ogun Hadareseri ọba Soba.

1. Kro 18