1. Kro 17:4-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Lọ, si sọ fun Dafidi iranṣẹ mi pe, Bayi li Oluwa wi, Iwọ kò gbọdọ kọ́ ile fun mi lati ma gbe.

5. Nitori emi kò ti igbe inu ile lati ọjọ ti mo ti mu Israeli gòke wá titi fi di oni yi; ṣugbọn emi nlọ lati agọ de agọ, ati lati ibugbe kan de keji.

6. Nibikibi ti mo ti nrin larin gbogbo Israeli, emi ha sọ̀rọ kan fun ọkan ninu awọn onidajọ Israeli, ti emi ti paṣẹ fun lati ma bọ awọn enia mi, emi ha ti wipe, Ẽṣe ti ẹnyin kò fi kọ́ ile igi kedari fun mi bi?

7. Njẹ nitorina bayi ni iwọ o wi fun Dafidi iranṣẹ mi, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, Emi mu ọ kuro ni pápá oko-tutu, ani kuro lati ma tọ agutan lẹhin, ki iwọ ki o le ma ṣe olori awọn enia mi Israeli.

8. Emi si ti wà pẹlu rẹ ni ibikibi ti iwọ ba lọ, emi si ti ké gbogbo awọn ọta rẹ kuro niwaju rẹ, emi o si ṣe ọ li olorukọ kan, bi orukọ awọn enia nla ti o ti wà li aiye.

1. Kro 17