20. Oluwa, kò si ẹniti o dabi rẹ bẹ̃ni kò si Ọlọrun miran lẹhin rẹ, gẹgẹ bi gbogbo eyi ti awa ti fi eti wa gbọ́.
21. Orilẹ-ède kan wo li o wà li aiye ti o dabi enia rẹ, Israeli, ti Ọlọrun lọ irapada lati ṣe enia on tikararẹ, lati ṣe orukọ fun ara rẹ nipa ohun ti o tobi ti o si lẹ̀ru, ni lile awọn orilẹ-ède jade kuro niwaju awọn enia rẹ, ti iwọ ti rapada lati Egipti jade wá?
22. Nitori awọn enia rẹ Israeli li o ti ṣe li enia rẹ titi lai; iwọ Oluwa, si di Ọlọrun wọn.
23. Njẹ nisisiyi, Oluwa! jẹ ki ọ̀rọ ti iwọ ti sọ niti iranṣẹ rẹ, ati niti ile rẹ̀ ki o fi idi mulẹ lailai, ki iwọ ki o si ṣe bi iwọ ti wi.
24. Ani, jẹ ki o fi idi mulẹ, ki a le ma gbé orukọ rẹ ga lailai, wipe, Oluwa awọn ọmọ ogun li Ọlọrun Israeli, ani Ọlọrun fun Israeli; si jẹ ki ile Dafidi iranṣẹ rẹ ki o fi idi mulẹ niwaju rẹ.