1. Kro 16:36-41 Yorùbá Bibeli (YCE)

36. Olubukún li Oluwa Ọlọrun Israeli lai ati lailai. Gbogbo awọn enia si wipe, Amin, nwọn si yìn Oluwa.

37. Bẹ̃ li o fi Asafu ati awọn arakunrin rẹ̀ silẹ nibẹ niwaju apoti ẹri majẹmu Oluwa lati ma jọsìn niwaju apoti ẹri na nigbagbogbo, bi iṣẹ ojojumọ ti nfẹ.

38. Ati Obed-Edomu pẹlu awọn arakunrin wọn, enia mejidilãdọrin; ati Obed-Edomu ọmọ Jedutuni, ati Hosa lati ma ṣe adena:

39. Sadoku alufa, ati awọn arakunrin rẹ̀, awọn alufa, niwaju agọ Oluwa, ni ibi giga ti o wà ni Gibeoni,

40. Lati ma ru ẹbọ sisun si Oluwa lori pẹpẹ ẹbọ sisun nigbagbogbo li owurọ ati li alẹ, gẹgẹ bi gbogbo eyi ti a kọ ninu ofin Oluwa, ti o pa li aṣẹ fun Israeli;

41. Ati pẹlu wọn Hemani ati Jedutuni, ati awọn iyokù ti a yàn, ti a si pe li orukọ, lati ma fi ìyin fun Oluwa, nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai;

1. Kro 16