1. Kro 16:27-34 Yorùbá Bibeli (YCE)

27. Ogo on ọlá wà niwaju rẹ̀; agbara ati ayọ̀ mbẹ ni ipò rẹ̀.

28. Ẹ fi fun Oluwa, ẹnyin ibatan enia, ẹ fi ogo ati ipa fun Oluwa.

29. Ẹ fi ogo fun Oluwa ti o yẹ fun orukọ rẹ̀: mu ọrẹ wá, ki ẹ si wá siwaju rẹ̀: ẹ sin Oluwa ninu ẹwà ìwa-mimọ́.

30. Ẹ warìri niwaju rẹ̀, gbogbo aiye aiye pẹlu si fi idi mulẹ ti kì o fi le yi.

31. Jẹ ki awọn ọrun ki o yọ̀, si jẹ ki inu aiye ki o dùn; si jẹ ki a wi ninu awọn orilẹ-ède pe, Oluwa jọba.

32. Jẹ ki okun ki o ma ho, ati ẹkún rẹ̀: jẹ ki papa-oko tùtu ki o yọ̀, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀.

33. Nigbana ni awọn igi igbo yio ma ho niwaju Oluwa, nitori ti o mbọ wá ṣe idajọ aiye.

34. Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa, nitori ti o ṣeun: nitoriti ãnu rẹ̀ duro lailai.

1. Kro 16