5. Nigbati ẹniti o ru ihamọra rẹ̀ si ri pe Saulu kú, on na pẹlu si ṣubu le idà rẹ̀, o si kú.
6. Bẹ̃ni Saulu kú, ati awọn ọmọ rẹ̀ mẹtẹta, gbogbo ile rẹ̀ si kú ṣọkan.
7. Nigbati gbogbo awọn ọkunrin Israeli ti o wà ni pẹtẹlẹ ri pe nwọn sá, ati pe Saulu ati awọn ọmọ rẹ̀ kú, nwọn fi ilu wọn silẹ, nwọn si sá: awọn ara Filistia si wá; nwọn si joko ninu wọn.
8. O si ṣe ni ijọ keji, nigbati awọn ara Filistia de lati wá bọ́ awọn okú li aṣọ, nwọn si ri Saulu pẹlu, ati awọn ọmọ rẹ̀ pe; nwọn ṣubu li òke Gilboa.
9. Nwọn si bọ́ ọ li aṣọ, nwọn si gbé ori rẹ̀ ati ihamọra rẹ̀, nwọn si ranṣẹ si awọn ara Filistia yika, lati mu ihin lọ irò fun awọn ere wọn, ati fun awọn enia.