31. Jeturi, Nafiṣi, ati Kedema. Wọnyi li awọn ọmọ Iṣmaeli.
32. Ati awọn ọmọ Ketura, obinrin Abrahamu: on bi Simrani, ati Jokṣani, ati Medani, ati Midiani, ati Iṣbaki, ati Ṣua. Ati awọn ọmọ Jokṣani: Ṣeba, ati Dedani.
33. Ati awọn ọmọ Midiani: Efa, ati Eferi, ati Henoki, ati Abida, ani Eldaa. Gbogbo wọnyi li awọn ọmọ Ketura.
34. Abrahamu si bi Isaaki. Awọn ọmọ Isaaki; Esau ati Israeli.
35. Awọn ọmọ Esau; Elifasi, Reueli, ati Jeusi, ati Jaalamu, ati Kora.
36. Awọn ọmọ Elifasi; Temani, ati Omari, Sefi, ati Gatamu, Kenasi, ati Timna, ati Amaleki.
37. Awọn ọmọ Reueli: Nahati, Sera, Ṣamma, ati Missa.
38. Ati awọn ọmọ Seiri; Lotani, ati Ṣobali, ati Sibeoni, ati Ana, ati Diṣoni, ati Esari, ati Diṣani.
39. Ati awọn ọmọ Lotani; Hori, ati Homamu: Timna si ni arabinrin Lotani.